Mrs D.A Fasoyin, a well-known gospel artist, presents a beautiful song called ‘Bi Mo Ba Fowo Kan Iseti Aso Re’ This song is a special way to show love and respect to God, with lovely and catchy music.
It’s not just regular music; it’s like a bridge that connects people to something heavenly. Enjoy this amazing musical journey, get this unique song, and share the joy with your friends and family.”
Ara mi yo ya gaga – C.A.C Good Woman Choir, Ibadan. Led By Mrs D.A Fasoyin
Bi mo ba f’õwõkan isęti asõ rę
Bi mo ba f’õwõkan isęti asõ rę
Bi mo ba f’õwõkan isęti asõ rę
Ara mi yio ya gaga, ara mi yio ya gaga
Igbagbõ la fi n rire gba lõwõ Baba
F’igbagbõ rõ m’ęni to le gba õ, arakunrin
F’igbagbõ rõ m’ęni to le gba õ, arabinrin
Gba t’iji aye ba yi lu o, sa gbękęle
Ko gbogbo aniyan rę l’Oluwa, sa ti gbagbõ
Obinrin onisun ęję, to f’igbagbõ tõ Jesu wa nibę lo rire gba
Isun ęję si duro lai t’ori p’o gbagbõ
Ara rę si ya gaga, ara rę si ya gaga
Bi mo ba f’õwõkan isęti asõ rę
Bi mo ba f’õwõkan isęti asõ rę
Bi mo ba f’õwõkan isęti asõ rę
Ara mi yio ya gaga, ara mi yio ya gaga
Nipa Igbagbõ, Abęli rubõ s’Õlõrun
Nipa igbagbõ, Enõku ba Õlõrun rin
Nipa igbagbõ, Abraham d’õrę Õlõrun
Nipa igbagbõ ni Noha d’olododo
O f’eti si õrõ Õlõrun
N’igba t’o kan õkõ igbala
Ikun omi de, õpõ si s’egbe
Kiki awõn to gbõ ti Noha nikan ni wõn la
Namani f’igbagbõ wę ninu omi, o d’asęgun
Iwõ arakunrin (Sa ti f’igbagbõ rõ m’Oluwa)
Iwõ arabinrin (Sa ti f’igbagbõ rõ m’Oluwa)
B’ogun aye ba de (Sa ti f’igbagbõ rõ m’Oluwa)
B’ogun õta ba de (Sa ti f’igbagbõ rõ m’Oluwa)
B’o j’owo lo n fę. (Sa ti f’igbagbõ rõ m’Oluwa)
B’o j’õmõ lo wu õ (Sa ti f’igbagbõ rõ m’Oluwa)
B’o ję ‘le lo fę kõ (Sa ti f’igbagbõ rõ m’Oluwa)
B’o j’owo lo fę se (Sa ti f’igbagbõ rõ m’Oluwa)
Iwõ ti ko ri ję (Sa ti f’igbagbõ rõ m’Oluwa)
Iwõ ti ko ri mu (Sa ti f’igbagbõ rõ m’Oluwa)
Agan ma ronu mõ(Sa ti f’igbagbõ rõ m’Oluwa)
Babalawo ko le se
Onisegun ko le se
Adahunse ko le s’õmõ f’igbagbõ rõ m’Oluwa
Ninu Bibeli, Ana f’igbagbõ rõ m’Oluwa
Agan r’õmõ gba t’ori p’o gbagbõ
Õlõrun f’Ana l’õmõ ara rę si ya gaga
Bi mo ba f’õwõkan isęti asõ rę
Bi mo ba f’õwõkan isęti asõ rę
Bi mo ba f’õwõkan isęti asõ rę
Ara mi yio ya gaga, ara mi yio ya gaga